Alàkóso ilé iṣé Awọn Oníròyìn fún Orílẹ̀-èdè (NAH) Mallam Ali Muhammad Ali ti rọ àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti má lo fún àyẹ̀wò ni gbogbo ìgbà ki wọn ba le mọ ipò tí ìlera wọn wa.
Ali ni àyẹwò ìgbà gbogbo gbọdọ jẹ ohun tí yóò mu wá lọkàn nitori ìlera wa
O ní nípa àyẹ̀wò a lè kojú àwọn àìsàn tí o n bá àgọ ará jà ní kíákíá tí ènìyàn yóò sì gba ìtọjú pẹ̀lú.
O wa tun gbà àwọn ènìyàn lámọ̀ràn láti má mu omi, jẹ oúnjẹ tí yóò sara lóore.