Olùránlọ́wọ́ fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ Peter Obi Media, POMR ti sọ pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ kiri pé ó fẹ́ fi ẹgbẹ́ Labour, LP, tí ó ti díje fún ààrẹ, ní 2023 sílẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ o.
Olùránlọ́wọ́ fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ sí Obi, Ọgbeni Michael Nwolisa ninu alaye kan ni a Abuja, ṣapejuwe iroyin yii bii irọ ati ẹtan.
O sọ pe iroyin kii ṣe otitọ ti ko si wa lati ọdọ Obi tabi “Obidient” bi koṣe lati ọdọ awọn eke ti wọn fẹ fa ede aiyede sinu ẹgbẹ naa.
O ni awọn ti wọn fẹ fa ede aiyede sinu ẹgbẹ LP jẹ ọta ijọba tiwantiwa to foju han gbangba.
Gẹgẹ bi oi ti sọ, Obi dojukọ pipese agbegbe ti yoo faaye gba ijọba bo ṣe yẹ ko ri, lai si ibọ lọwọ iya jijẹ.