Àjọ ìlera tó n mójú àgọ́ ará (NHED) pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ àwọn ènìyàn láwùjọ sọ wí pé jíjẹ iyọ àjẹjù leè mú kí èmi ènìyàn kúrò sí igba tí yóò lo láyé .
Dọ́kítà Jerome Mafeni, NHED to je adari, àti abanidamoran fún iponlogo edi iyọ jije kun sọ wí pé bí ènìyàn bá jẹ iyọ ni àjẹjù o léwu fún àgọ ará.
Ni ọjọ́ ìṣẹgun ni ilu Abuja nibi ìpàdé ní ọ̀rọ̀ náà ti jáde.
Mafeni sọ wí pé àsìko tí tó báyìí fún àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti mọ ẹwu to wa nínú ki ènìyàn jẹ iyọ àjẹjù.
Ó ní, ó wa ń fa àisìán ọkàn, ifunpa, àìsàn rọpárọsẹ̀ àti bẹẹ bẹẹ lọ.
Ó ní o tí to mílíọ̀nù àwọn ènìyàn mejidinlogun tí o ti pàdánù èmi wọn Látàrí iyọ àjẹjù.
Ó ní àwọn yóò ṣàlàyé fun àjọ tó n mójú tó ọ̀rọ̀ óúnje ati ògùn ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti rí wí pé wọn ṣe atilẹyin fun eto náà