Wọ́n ti gbajúgbajà ilé ìtajà Abuja kan pa fún ẹ̀sùn àìsedéédé owó ọjà
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ètò ìdáàbòbò ìdíje àti àwọn olùrajà lápapọ̀ (FCCPC), ti ti gbajúgbajà ilé ìtajà tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Sahad Stores Limited, lórí ẹ̀sùn ìyànjẹ, àti àṣìlọ́nà owó ìtajà.
Wọ́n ti gbajúgbajà ilé ìtajà Sahad ti o wa ni Area 11, Garki , ni Abuja pa nitori ẹsun pe iyatọ wa ninu iye owo ti wọn patẹ sori ọja ati iye ti oluraja yoo san.
Ọgbẹni Abdullahi sọ pe iṣewadi akọkọ fihan pe awọn oluṣakoso ile itaja naa n yan oluraja jẹ.
O tun ṣalaye pe lasiko iṣewadii FCCPC pe awọn oluṣakoso Sahad stores lati wa ṣalaye bi iyatọ ṣe wa ninu iye owo ọja ninu ile itaja wọn, ṣugbọn wọn kọ lati yọju.
Nigba ti o n tunbọ fẹsẹ ipinnu rẹ mulẹ lati daabobo awọn oluraja, Ọgbẹni Abdullahi wa kilọ pe eleyii yoo jẹ ki awọn eniyan ati ile iṣe ti n yan oluraja jẹ o fọwọ sibi tọwọọ gbe.
O tun wa fikun un pe ile itaja naa yoo wa ni titipa titi wọn yoo fi pari awọn iwadi to ku.