Take a fresh look at your lifestyle.

Ize-Iyamu yọwọ́ nínú ìdíje gómìnà APC Edo

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

158

Ìkan lára àwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), fún ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo ní ọjọ́ kọkànlé-lógún, oṣù kẹsàn án Àlùfáà Osagie Ize-Iyamu, ti jáwọ́ nínú ìdíje náà bí ìdìbò abẹ́lé rẹ̀ yóò ṣe wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Ize-Iyamu ṣalaye eyi nibi ipade awọn akọroyin ni Benin, olu ilu ipinlẹ  Edo ni ọjọ Ẹti.

O sọ pe erongba oun lati yọwọ dun oun gidi gan an, ṣugbọn oun gbo igbesẹ naa lẹyin ijumọsọrọ pẹlu awọn ọrọ, ẹbi ati awọn oloṣelu ẹgbẹ oun.

O wa sọ nibayii pe, oun fọwọ sọya lati ṣatilẹyin fun eyikeyi oludije gomina fun ẹgbẹ APC to ba jawe olubori ninu ibo abẹle ọjọ Abamẹta.

Ize-Iyamu wa gboriyin fun aarẹ Tinubu ati awọn adari ẹgbẹ naa lapapọ fun isododo wọn ati ifọkan si eto ijọba tiwantiwa.

Awọn oludije APC ti ku mọkanla bayii fun idibo abele ọjọ Abamẹta, lẹyin ti Ize-Iyamu ti jawọ.

Awọn to ku lẹnu idije naa ni: Dennis Idahosa, Clem Agba, Monday Okpebholo, Lucky Imasuen, Anamero Dekeri, Gideon Ikhine ati Ajagun David Imuse, Ajagun fẹyinti Charles Airhiavbere, Oserheimen Osunbor, Blessing Agbomhere, ati Ernest Umakhihe.

 

Comments are closed.

button