Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdáàbòbò ará ìlú jẹ Ìjọba Nàìjíríà lógún

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

125

Mínísítà ìpínlẹ̀ fún ètò ààbò, Dókítà Bello Matawalle ti sọ pé ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu pàtàkì ìdáàbòbò àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè, èyí tí ó fàá tí ó fí ró ológun lágbára kí ó le ṣiṣẹ́ rẹ̀ bíi iṣẹ́.

O ni wọn ti rọ awọn ọga eleto aabo naa lati tunbọ fi agbara kun agbara fun iṣẹ aabo.

Minisita sọ eyi lẹyin awọn ọrọ ti ko dun metii gbọ ti n jade lati ẹnu awọn eniyan kan.

Dokita Matawalle wa kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ṣọra fun awọn ọrọ ti o le da wahala silẹ, si ijọba gẹgẹ bi o ṣe wa ninu alaye kan ti alakoso eto ibaraẹnisọrọ ati ajọṣepọ ara ilu, Henshaw Ogubike fi sita.

Dokita Matawalle tun wa ka awọn ilana oriṣiriṣi ti ijọba Tinubu ti pese silẹ lati ṣe atunṣe ati isọdọtun ọrọ aje wa ati daabobo ẹmi, igbe aye ati dukia awọn eniyan.

Minisita tun wa fi idi pataki iṣọkan mulẹ, wipe ohun ti o ba kan ọmọ Naijiria kan ti pa dandan lati kan gbogbo orilẹ-ede.

Comments are closed.

button