Ìgbìmọ̀ Olómìnira tó ń ṣètò ìdìbò lórílẹ̀-èdè (INEC), ti sọ pé òhun ti ṣetán fún àdìkù ìbò agbègbè inú ìlú Gúsù Enugu tí wọ́n sún ọjọ́ rẹ̀ sí Ọjọ́ọ́rú, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kejì.
Adari idanilekọ awọn oludibo ati ti isọri ipolongo INEC, Ọgbẹni Rex Achumie, sọ fun awọn akọroyin ni, ọjọ Iṣẹgun pe eto to peye ti to lori idibo naa.
Achumie ṣalaye pe igbimọ naa yoo gba awọn ohun elo to ṣe pataki lati ọdọ ile ifowopamọ apapọ lorilẹ-ede, (CBN) nisoju awọn ẹgbẹ oṣelu ati awọn to nii ṣe ninu eleto idibo ni deede agogo mẹta, ni ọjọ Iṣẹgun.
O sọ pe wọn yoo tọju awọn ohun elo pataki naa si olu ile iṣẹ INEC ti ipinlẹ, Enugu fun pinpin ki o to di agogo mejọ owurọ fun idibo. Gẹgẹ bi o ṣe sọ, iwe ipese esi ko ni mu wahala dani, ko si ni si aṣiṣe mọ.
Adiku naa ko le waye ni ọjọ kẹta oṣu keji mọ nitori aisi iwe ipese esi ni awọn ibudo idibo, leyi ti o mu ki wọn sun eto naa siwaju.