Wọn ti bura fun Sẹnetọ mẹta ti o ṣẹṣẹ bori ninu ibo adiku ni awọn agbegbe wọn, ni ọjọ́ Iṣẹgun, ni inu ile igbimọ.
Awọn Sẹnetọ naa gba aṣẹ iwọle sinu ọfiisi niwaju aarẹ ile igbimọ, Godswill Akpabio, lasiko ijoko.
Awọn Sẹnetọ naa ni: Ọmọ Ọba Pam Mwadkon ( ADP – Arewa Plateau), Ọjọgbọn Anthony Ani (APC-Gusu Ebonyi) ati Mustapha Musa (APC- Ila oorun Yobe).
Chinedu Akubueze, ti o jẹ Akọwe fun awọn Sẹnetọ ni o ṣe ibura fun awọn Sẹnetọ mẹta naa, ti o si mu wọn lọ si ori aga ijoko wọn ni sisẹ n tele lẹyin naa.