Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣoju, Tajudeen Abbas, ti rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ní sùúrù bí ìjọba ṣe ń ṣiṣẹ́ lórí àtúnṣe ìgbé ayé wọn.
O pe ipe yii lasiko ipade awọn oniroyin lagbaye lori ipo orilẹ-ede,ní Abuja, olu ilu Naijiria.
O sọ pe o n ka ijọba lara ti o si mọ inira awọn ọmọ Naijiria, ti o si ṣetan lati mu iyipada baa.
Aṣoju Abbas wa tọka si bi idokowo ṣe ri ninu ọrọ aje agbaye to bajẹ ati isuna ti ko to fun erongba ijọba lati fopin si ailaabo ni Naijiria.
Adari ile naa tun ṣalaye pe ile igbimọ naa mọ ipeninija ọrọ aje ti n koju agbegbe jakejado Naijiria.
O tun wa rọ awọn ọmọ Naijiria, lati Ariwa si Gusu, lati Gusu si iwọ oorun, lati fọwọsowọpọ sun atilẹyin ati iranlọwọ awọn eto ijọba.