Ààrẹ Tinubu gbóríyìn fún Super Eagles fún àṣeyege ìpele tí ó gbẹ̀yìn
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu, ti gbóríyìn fún Super Eagles ti Nàìjíríà fún àṣeyege ìpele tí ó gbẹ̀yìn nínú ìfagagbága ife orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀, tí Ivory Coast ṣagbátẹrù rẹ̀.
Nigba ti o n fesi lori àṣeyege ìpele tí ó gbẹ̀yìn nínú ifẹsẹwọnsẹ Super Eagles ti o waye ni Stade de la Paix, aarẹ Tinubu, lori ayelujara X rẹ, ti a mọ tẹlẹ si Twitter, gboriyin fun awọn ilumọọka naa, ti o si sọ pe wọn mu awọn ọmọ Naijiria yangan pẹlu ifaragba wọn lori papa.
Aarẹ wa rọ Super Eagles lati tunbọ gbiyanju ninu aṣekagba AFCON.

Naijiria yoo wa figagbaga pẹlu orilẹ-ede to ṣagbatẹru AFCON 2023, Ivory Coast, fun aṣekagba AFCON ni ọjọ Aikum, ọjọ kọkanla, oṣu keji, 2024.
Eleyi ri bayi nitori aṣeyege ookan si odo Ivory Coast si DR Congo ninu ifẹsẹwọnsẹ irọlẹ Ọjọọru.