Ìgbìmọ̀ olómìnira tí ń mójútó ètò ìdìbò lórílẹ̀-èdè, INEC ti kéde ìdádúró àwọn ìdìbò àdìkù tí ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn agbègbè kan nítorí ìdàrú, àìsedédé àti jíjí àwọn òsìṣẹ́ elétò ìdìbò gbé.
Igbimọ Kọmiṣọna lapapọ ati alaga, ti ibaraẹnisọrọ ati idanilẹkọ awọn oludibo, Sam Olumekun, sọ ninu alaye ti o ṣe fun awọn akọroyin pe awọn agbegbe ti ọrọ naa kan ni “Agbegbe ijọba apapọ Ikono/Ini, ti ipinlẹ Akwa Ibom State, ibudo idibo meji (Gbọngan Abule, EdemUrua 003 ni ijọba ibilẹ Ini ati Gbọngan Abule Mbiabong Ikot Udo 003 ni ijọba ibilẹ Ikono) nibi ti awọn oni jagidijagan ti gbe awọn ohun elo idibo salọ”.
Olumekun ṣalaye pe awọn ibi to ku ni “Gusu Enugu kinni ti agbegbe ipinlẹ, ipinlẹ Enugu, idaduro idibo ni awọn ibudo idibo mejọ nibi ti iwe esi ibo gangan ko ti wa nilẹ fun awọn oludibo lati ṣayẹwo rẹ ki ibo to bẹrẹ”.
O tun wa sọ pe, “awọn adugbo ti o kan ni apa ila oorun orilẹ-ede ni, agbegbe ijoba apapọ Kunchi/Tsanyawa, ipinlẹ Kano, idaduro ibo ni gbogbo awọn ibudo idibo mẹwaa ni ijọba ibilẹ Kunchi nitori igbogun, ibankanjẹ, ati idiwọ lati ọdọ awọn onijagidijagan”.