Àwọn òsìṣé elétò ààbò, òṣìṣẹ́ INEC gúnlẹ̀ lásìkò fún ìbò àdìkù ní ìpínlẹ̀ Ondo
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òsìṣé elétò ààbò ni ó ti gúnlẹ̀ sí Ikare-Akoko àti àyíká ìlú náà fún àdíkù ìbò fún ipò ilé ìgbìmọ̀ aṣojú fún Àríwá-Gúsù Akoko àti Àríwá-iwọ̀ oòrùn Akoko, ti agbègbè ìjọba àpapọ̀ ìpínlẹ̀ Ondo.
Ijabọ fi toni leti pe ni owurọ kutu ni agogo meje, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òsìṣé elétò ààbò ti wa ni oju ọna Pataki lati wọ Ikare-Akoko, ti o jẹ olu ile iṣẹ ijọba ibilẹ Gusu Akoko.
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo bii Agbofinro, ẹgbẹ ti n pese aabo fun ara ilu ati aabo Naijiria, NSCDC ati awọn oṣiṣẹ to n mojuto ọrọ Naijiria ni wọn ti wa ni awọn ipo to ṣe koko ni ilu naa ati ni awọn ibudo idibo, ati awọn ọkọ awọn eleto aabo ti n wolẹ kaakiri.
Ijabọ tun sọ pe awọn oṣiṣẹ igbimọ olominira ti n mojuto eto idibo lapapọ, INEC naa gunlẹ si awọn ibudo idibo ni Ikarẹ lasiko nigba ti awọn oludibo si n ṣe ayẹwo orukọ wọn ninu iwe orukọ ti wọn lẹ mọ ara ogiri ati patako ikawe.
Bakannaa, kosi tita rira ninu ilu nitori pe awọn ọja ati isọ ti wa ni titi pa, ti awọn alupupu kọọkan si n rin loju popo ni bii agogo meje aabọ owurọ.
Ibo adiku yii yoo di ipo ile igbimọ aṣoju fun Ariwa-Gusu Akoko ati Ariwa-iwọ oorun Akoko ni agbegbe ipinlẹ Ondo, ti Ọgbẹni Olubunmi Tunji-Ojo fi silẹ.
Ipo yii ṣi silẹ nigba ti aarẹ Bọla Tinubu yanTunji-Ojo ni Minisita fun ọrọ inu orilẹ-ede, ni oṣu kẹjọ 2023.