Ààrẹ Tinubu ṣèdárò pẹ̀lú ajagunfẹ̀yìntì Abdulsalam lórí ikú àbúrò rẹ̀
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti ṣèdárò pẹ̀lú olórí orílẹ̀-èdè nígbà kan rí, Ajagunfẹ̀yìntì Abubakar Abdulsalam lórí ikú àbúrò rẹ̀, Hajiya Salamatu Asabe.
Aarẹ ninu ifiranṣẹ idaro ti agbẹnusọ rẹ, Ajuri Ngelale buwọlu, o ba ẹbi naa kẹdun, ati awọn ti wọn banujẹ fun ipapoda naa.
Adari Naijiria wa gbadura pe ki ẹbi rẹ ri idunnu ninu ohun ti ti ṣe silẹ ati awọn iranti awọn ohun to dara to fi silẹ.