Take a fresh look at your lifestyle.

Tanzania ṣetán fún ìfẹ̀hónúhàn alátakò, pè fún àtúnṣe ètò ìdìbò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

291

Ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò pàtàkì ní Tanzania, Chadema, ti múra fún ìfèhónúhàn lórílẹ̀-èdè lórí òfin ètò ìdìbò tí wọ́n ń gbèrò, bí ìgbé ayé ṣe le, àti fífi àtúnṣe òfin orílẹ̀-èdè falẹ̀.

Niwọn igba ti awọn Agbofinro inu ilu Dar es Salaam ti fun wọn laye lati tẹsiwaju, wọn wa kiwọn nilọ lati ṣọra fun iwa ipa ati tẹmbelẹkun, gẹgẹ bi awọn ile iroyin agbegbe ṣe sọ.

Chadema kede pe wọn ri ifọwọsi ibeere yii gba nipasẹ ifẹnuko pẹlu awọn Agbofinro, ti wọn si yanana ifọkansi ifẹhonuhan ti yoo lọ wọrọwọ.

Ifẹhonuhan yii ni lati le ijọba lere, lati ṣe imuṣẹ awọn atunṣe ni mimura fun idibo gbogbogboo ti n bọ lọna kiakia.

Ẹgbẹ alatako diidii lodi si ofin eto idibo mẹta ti wọn gbe kalẹ ni ile igbimọ ni oṣu kọkanla to kọja, ti wọn si n pe fun idapada rẹ lori pe wọn kọ iyan awọn to nii ṣe to pọ kere.

Fun idi eyi awọn ifẹhonuhan yii yoo sami ifẹhonuhan alakọọkọ ni Tanzania lati igba ti aarẹ Samia Suluhu Hassan ti gori oye ni oṣu kẹta 2021.

Comments are closed.

button