Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ọmọdé tí kò sí ní ilé ìwé mọ́: Nasarawa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ Àgbáyé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

142

Ìjọba ìpínlẹ̀ Nasarawa ti sọ pé òhun ti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ Àgbáyé láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn òbí tí kò ní owó tó tó láti rán àwọn ọmọ wọn lọ sí ilé ìwé ní ìpínlẹ̀ náà.

Kọmiṣọna ipinlẹ fun eto Ẹkọ, Dokita John Mamman, sọ eyi nibi ipari idanilẹkọọ ipe lori Ẹkọ, ilera, ati idọgba akọ ati abo ọlọjọ meji, ti ile iṣẹ idagbasoke eniyan pẹlu Africa Human Capital Development Plus ṣe agbekalẹ rẹ.

Dokita Mamman sọ pe dida awọn ọmọ to ti fi ile iwe silẹ pada si yara ikawe ti wa lookan aya gomina ipinlẹ naa, Abdullahi Sule, ti o si n fi daniloju pe ni awọn osu ti n bọ, riri awọn ọmọdr ti ko kawe loju titi yoo dinku gidi gan an ni, ti ko ba ni dopin patapata.

 

Comments are closed.

button