Take a fresh look at your lifestyle.

Àtúnṣe Gbogbo Ọ̀nà Ló Jẹ́wa Lógún – David Umahi

249

 

Mínísítà fún àkànṣe iṣẹ orílẹ̀-èdè yìí, David Umahi ti sọ pé àtúnṣe gbogbo ọ̀nà jakejado ilẹ̀ yi ló jẹ àwọn lógún.
” Gbogbo nǹkan ni ọ̀nà jẹ́, tí ẹ bá tú ọ̀nà se, ètò ààbò, ọ̀gbìn, ẹ̀kọ́, ọrọ̀ ajé àti ayọ̀ àwọn ènìyàn ni ẹ ti tún ṣe.”

Ó sọ èyí nígbà tó pade Mínísítà ètò ọ̀rọ̀ ààbò, Mohammed Badaru Abubarkar, ati olori ologun, ogagun Taoreed Lagbaja ni Minisiri eto iṣẹ ni Abuja, Olu ilu Naijiria.

Ó fi kun pe, lára eto “Ìrètí ọ̀tun” ìjọba Bola Ahmed Tinubu ni títú ọ̀nà se ti ó sí máa jẹ́kí ètò ààbò fẹsẹ̀ walẹ̀.

Ọ̀gá àgbà awọn ọmọ ogun ilẹ̀ wa sàlàyé pe ìpàdé pẹ̀lú Mínísítà ọrọ àkànṣe iṣẹ́ dá lórí àtúnṣe àwọn ohun èèlò ti yóò jẹ́kí iṣẹ́ ológun já fáfá ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó tún fi dá Mínísítà lójú àtìlẹyìn rẹ̀ nípa jíjẹ́ “Ìrètí ọ̀tun” wá sí ìmúsẹ nípa títú ọ̀nà Orílẹ̀-èdè yí se.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button