Take a fresh look at your lifestyle.

Gombe kéde ìbẹ́sílẹ̀ ààrùn àwọn ẹranko

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

220

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Gombe ti kéde ìbẹ́sílẹ̀ ààrùn àwọn ẹranko ní ìpínlẹ̀ náà.

Kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera, Dókítà Habu Dahiru, sọ èyí lásìkò tí ó ń ṣàlàyé fún àwọn oníròyìn pé, arákùnrin aláárẹ̀ kan tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́èdọ́gbọ̀n, ti rin ìrìn àjò lọ sí ìpínlẹ̀ Adamawa fún ọ̀sẹ̀ méjì, níbi tí wọ́n ti fura síi pé ó ti kó ààrùn ẹranko náà.

Drokita Dahiru sọ pẹ lẹyin ti o de ni ami aarun naa wa n yọ lara rẹ, bii ara gbigbona ti wọn si gba wọle sinu ile itọju kan, ki wọn to tun dari rẹ lọsi ile iwosan ikọni ti ijọba apapọ, Gombe, nibi ti wọn ti ṣe ayẹwo fun ti wọn si fi idi rẹ mulẹ pe o si ni aarun ẹranko.

 “Nigba ti wọn fidiẹ mulẹ pe ẹni ọhun ni aarun naa, wọn mu lọ si aaye ọtọ ti ohnu nikan yoo dawa fun itọju,” Dokita Dahiru sọ bayii.

O tun wa sọ siwaju pe wọn tun ti gba ẹjẹ awọn eniyan mẹẹdogun, ti wọn ni aṣepọ pẹlu rẹ, fun ayẹwo ni ile ayẹwo.

Kọmiṣọna ipinlẹ Gombe fun eto ilera wa sọ pe ẹgbẹ iṣakoso iṣẹlẹ ti ile iṣẹ ijọba apapọ, ti ipinlẹ ti n lọ kaakiri ilu naa lati wa awọn ti o ba ni aarun ọhun.

Comments are closed.

button