Take a fresh look at your lifestyle.

Gombe: NSCDC ké gbàjarì lórí àkóràn ààrùn tí kò gbóògùn láàrin àwọn obìnrin

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

186

Adarí ẹgbẹ́ tí ń mójútó ààbò Nàìjíríà àti ìdáàbòbò ará ìlú (NSCDC), ti ìpínlẹ̀ Gombe ti ké gbàjarì, pé àwọn ọmọ bìnrin kan tí wọ́n ti kó ààrùn kògbóògùn HIV/AIDS ti ya wọ ìpínlẹ̀ Gombe, olú ìlú pẹ̀lú èròńgbà láti kóo ran àwọn ọkùnrin tí kò mọ̀ pé wọ́n ní irú ààrùn náà.

Adari gbogbogboo NSCDC, Mohammed Bello Muazu, sọ pe wọn mọ idi eleyi lẹyin ti wọn mu arakunrin agbalagba kan ti o jẹ ọmọ ọdun marunle-lọgọrin (wọn fi orukọ bo laṣiri),  ti a gbọ pe o ti tan aimọye ọdọ binrin ba laṣepọ ti o si jẹ pe lẹyin ayẹwo wọn ri pe o ni aarun kogboogun yii ati awọn iyawo mẹrin ti o ni.

Adarí ẹgbẹ́ tí ń mójútó ààbò Nàìjíríà àti ìdáàbòbò ará ìlú (NSCDC), ti ipinlẹ Gombe ni o ke gbajari yi, ti o si n kilọ fun awọn ọkunrin ti n wa awọn obinrin ati ọbọ binrin ti ko wọn lati ṣọra ki wọn maa ba ko si pampẹ awọn eniyan buruku yii.

Adari ipinlẹ naa wa kilọ fun gbogbo ara ilu lati ṣọra fun ibalopọ lọna ti ko tọ tabi ki wọn lọ ṣe ayẹwo ipo wọn ki wọn to maa ba ẹnikankan ni aṣepọ.

Muhammad Muazu tun wa ṣalaye pe adari naa tun n koju awọn ipeninija to burujai kan pẹlu awọn ile iṣẹ ti kii ṣe tijọba ti n ṣatilẹyin fun ibaṣepọ ati igbeyawo akọ ati akọ tabi abo ati abo, nnkan ti o ti n wọpọ ni ipinlẹ naa ti awọn ọdọ ti ko to ọdun mẹedọgbọn naa si lọwọ si.

Comments are closed.

button