Take a fresh look at your lifestyle.

Adarí ilé ìgbìmọ Plateau fi àtìlẹyìn ilé aṣòfin dá gómìnà Mutfwang lójú

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

171

Adarí, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Plateau , Gabriel Dewan, ti fi àtìlẹyìn ilé aṣòfin dá gómìnà Caleb Mutfwang lójú láti jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí. Dewan ṣe idaniloju yi ni ọjọ Abamẹta, nibi igbalejo lati yẹ Mutfwang si lẹyin aṣeyege rẹ ni ile ẹjọ giga.

Adari naa sọ pe ogun ile ẹjọ ti pari, asiko ti to fun iṣejọba ati fun aṣofin lati sa gbogbo ipa wọn fun ilọsiwaju ipinlẹ naa.

O wa ṣalaye aṣeyege Mutfwang bii aṣeyege fun awọn eniyan Plateau.

Eyi ni aṣeyọri fun ipinlẹ, ati pe, mo fẹ fi asiko yii da gbogbo wa loju pe asiko oṣelu ti pari.

Asiko iṣejọba niyi, ti mo si n fi da ọ loju pe ni tiwa ni ile asofin, ati bii adari ile igbimọ, oa o sa gbogbo ipa wa lati ri pe o ṣe aṣeyege.

A o ṣe atilẹyin ti gomina nilo fun lati wa ọkọ ipinlẹ yi siwaju.

Comments are closed.

button