Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Kebbi Ti Ná Bílíọ̀nù Márùn-ún Náírà Láti Ṣe Àtìlẹ́yìn Fún Àwọn Àgbẹ̀.

202

Ìjọba ìpínlẹ̀ Kebbi sọ wí pé àwọn tí na Bílíọ̀nù Márùn-ún Náírà láti fi ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn àgbẹ̀ ni ìpínlẹ̀ náà.

Wọn ní lára owó yìí ni àwon tí pèsè ètò ààbò fún àwọn àgbẹ̀ pẹ̀lú.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi Dọ́kítà Mohammed Idris lo sọ èyí di mímọ̀ nígbà tí o ṣe ìbẹ̀wò sí Mínísítà fún ètò Ọ̀gbìn Ṣẹ́nitọ̀ Abubakar Kyari ní Ìlú Abuja.

Gómìnà ní ọ̀nà mẹta ni ìjọba òun dojukọ fún ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà, Ètò Eko ọ̀gbìn, Ètò Eko àti Ètò Ààbò.

O ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ìjọba òun n ṣètò àwọn nkán ọ̀gbìn bi àgbàdo, ìrẹsì, ọkà bàbà àti bẹẹ bẹẹ lọ ti àwọn yóò Pin fún àwọn àgbẹ̀ lati gbin.

Gómìnà ní àwọn tún ti ṣe ètò bi ina yóò ṣe wà fún àwọn àgbẹ̀ nipa ẹrọ amunawa ti òrùn tó tó ẹgbẹ̀rún mefa ti ijoba òun ti rà báyìí.

O ni bákannáà ijoba òun yóò ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ilé ìjọba àpapọ̀ fún ètò ọgbin àti ààbò oúnjẹ fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ìpínlẹ̀ náà.

Comments are closed.

button