Take a fresh look at your lifestyle.

NYSC ní irọ́ ni o àwọn adigunjalè kò pa ọmọ Àgùnbánirọ̀ kankan o

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

169

Àwọn olùṣàkóso ẹgbẹ́ Àgùnbánirọ̀ lápapọ̀ ( NYSC) ní Nàìjíríà ti kọ ìjábọ̀ àwọn oníròyìn pé àwọn adigunjalè pa ọmọ Àgùnbánirọ̀ kan nígbà tí ó ń lọ láti ìpínlẹ̀ Kaduna sí Katsina, Àríwá iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà fún oṣooṣù biometric clearance.

Nigba ti o n fesi si iroyin to n lọ lọwọ lori ayelujara, Adari, eto iroyin ati ibaraẹniṣepọ ara ilu fun NYSC, Ọgbẹni Eddy Megwa ṣalaye bayii  kosi otitọ ninu ọrọ naa biko ṣe atotonu awọn alayinike onkọwe, ti o fẹ fa airoju laarin ara ilu.

Ki a sọ otitọ ọrọ naa, Ọmọ ẹgbẹ Agunbanirọ kan ti n jẹ Mamudo Sa’idu Obaje KT/23B/1153, ti n sin orilẹ-ede baba rẹ ni Government Girls’ College ní Katsina, n rin irin ajo lati Kaduna sí Katsina ní Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, osu kinni, 2024 ti ọkọ to wọ si ṣe ijamba ní Gayaza ní ijọba ibilẹ  Kankia ti ipinlẹ Katsina pẹlu awọn ero ọkọ to ku.

Meji ninu awọn ero ọkọ naa padanu ẹmi wọn ati Agunbanirọ yii ninu ijamba ọkọ naa.”

Ọgbẹni Megwa tun wa sọ siwaju pe, awọn ọmọ ẹgbẹ NYSC lorilẹ-ede lapapọ n ṣe ọfọ aburu ti o ṣẹlẹ yii, Awọn oluṣakoso naa wa n ṣedaro pẹlu ẹbi Agunbanirọ naa ti o di oloogbe lẹnu sisin orilẹ-ede baba rẹ.

Awọn oluṣakoso NYSC wa rọ awọn agberoyin lati maa ri idi ododo ki wọn to maa fi iroyin safẹfẹ, ki wọn maa baa le da wahala silẹ lorile-ede.

 

Comments are closed.

button