Mínísítà fún ọ̀rọ̀ inú ìlú, Àwọn tó kù lọ fún ìbánisọ̀rọ̀ ààrẹ ní gbogbo ìgbà ní Villa
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ inú ìlú Olubunmi Tunji-Ojo, pẹ̀lú àwọn mínísítà mẹ́ta mìíràn, wà ní ìjókòí ní gbọ̀ngàn ààrẹ ní Villa , ní ọjọ́ Ìṣégun fún ìbánisọ̀rọ̀ ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu tí máa á wáyé ní gbogbo ìgbà.
Awọn minisita to tun wa nibẹ ni; Omidan Hanatu Musawa (Ọna iṣẹ ati iṣẹda ọrọ aje ), Shuaibu Audu (Idagbasoke Irin) ati Adebayo Adelabu (Ina).
Tunji-Ojo sọ pe oun ṣabẹwo si aarẹ fun ibanisọrọ aarẹ gbogbo igba lori idagbasoke ni ile iṣẹ ijọba apapọ naa.
Agbẹnusọ fun ile iṣe aarẹ ṣalaye pe wọn ko pe Mínísítà fún ọ̀rọ̀ inú ìlú, Ọgbẹni Tunji-Ojo bi iroyin ṣe sọ, ṣugbọn o ti ṣe abẹwo, gẹgẹ bii awọn ẹlẹgbẹ rẹ mẹta to ku, fún ìbánisọ̀rọ̀ ààrẹ to maa n waye ni gbogbo igba.
Ni bayii, Mínísítà fún ọ̀rọ̀ inú ìlú, Tunji-Ojo, ti sọ ni irọlẹ ọjọ Aje nigba ti wọn gbaa lalejo lori eto olojoojumọ lori ohun to n lọ lorilẹ-ede, Politics Today, sọ pe oun da ile iṣẹ ti wọn ni oun ni, New Planet Projects Limited ni bii ọdun mẹwaa sẹyin, ṣugbọn oun kọwe fiṣẹ silẹ bii adari rẹ ni 2019 nigba ti o dije fun ile igbimọ asoju.