Take a fresh look at your lifestyle.

Alága APC ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú gómìnà Alia lórí àṣeyọrí ilé ẹjọ́ gíga

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

268

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú tí ń ṣèjọba All Progressives Congress (APC), Dókítà Abdullahi Umar Ganduje ti kí gómìnà Hyacinth Alia ti ìpínlẹ̀ Benue lórí àṣeyọrí ilé ẹjọ́ gíga.

Ganduje ninu alaye kan lati ọdọ Akọwe agba rẹ fun eto iroyin, Edwin Olofu sọ pe ẹjọ naa lati ile ẹjọ giga fidi ẹ mulẹ pe aṣeyege ninu idibo gbogbogboo 2023 naa tọ si gomina Alia.

Ganduje wa rọ awọn ẹgbẹ alatako ati awọn ọmọ ipinlẹ Benue lati fọwọsowọpọ fun idagbasoke ibaraẹniṣepọ ọrọ-aje ni ipinlẹ naa.

Mo ki ọ ku oriire fun aṣeyọri rẹ ati aṣayege bi o ṣe n gbaradi lati bẹrẹ ojuṣe ati ipeninija iṣe nla tuntun ti o gba.

Mo wa fẹ fi da ọ loju ati awọn eniyan ipinlẹ Benue pe a o tunbọ maa ṣatilẹyin fun ẹgbẹ naa,” o ṣalaye.

O wa sọ pe asiko ti to fun awọn eniyan ipinlẹ Benue lati gbogbo ẹgbẹ oṣelu ati awọn isọri ẹya lari dide iranlọwọ fun ọ bi gomina ti ọlọrun yan.

Comments are closed.

button