Take a fresh look at your lifestyle.

Agbófinró gba àwọn afaragbà sílẹ̀, mú àwọn afurasí ní ìpínlẹ̀ Anambra

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

160

Agbófinró ti ìpínlẹ̀ Anambra ti gba àwọn afaragbà méjì tí wọ́n jí gbé sílẹ̀, tí wọ́n sì tún ti mú àwọn afurusí bíi ọgbọ̀n pẹ̀lú àwọn ajínigbe, adigunjalè, Àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn àti àwọn jàǹdùkú tí wọ́n ń da ìpínlẹ̀ náà rú lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.

Kọmiṣọna Agbofinro ti ipinlẹ Anambra, CP Aderemi Adeoye sọ eyi lasiko ibawọn oniroyin sọrọ ni olu ile iṣẹ Agbofinro ni Awka, ní ọjọ Aje, nigba ti wọn n foju awọn afurasi naa han ati awọn ohun elo ti wọn gba lọwọ wọn, ti o si fikun un pe wọn mu wọn laarin ọjọ kinni, oṣu kejila 2023 titi di ọjọ oni.

Kọmiṣọna naa tun sọ pe wọn ti ṣe agbakalẹ awọn afaragba meji ti wọn fipa gbe lọ lasiko oniruuru ikoju pẹlu awọn ọdaran naa, nigba ti awọn oṣiṣẹ Agbofinro kan si farapa.

CP Adeoye ṣalaye pe ninu awọn afurasi ọgbọn, mejila jẹ ajinigbe, mẹsan jẹ adigunjale, mẹfa jẹ ẹlẹmi okunkun ti awọn mẹta si jẹ alakatakiti, o ni pe wọn mu wọn ni agbegbe ọtọọtọ lẹyin ti awọn kan yọ sọ fun wọn.

O fi kun un pe wọn ri ọkọ mọkanla ti wọn ji gbe gba, ibọn mejila ati ọta ibọn ogoji lọwọ awọn ọdaran naa.

Comments are closed.

button