Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Tí Ó Ń Fi Owó Ṣe Ìrànlọ́wọ́ Fún Àwọn Ènìyàn Ṣe Ìrànlọ́wọ́ Fún Àwọn Àgbè Ni Ìpínlẹ̀ Enugu.

161

Ọgá àgbà pátápátá fún ilẹ iṣé Paschal -Rico, Olóyè Pascal Aneke àti Ọ̀gbẹni Sunday Ozokolo láti Orílẹ̀-èdè Switzerland ni ọjọ́ ìsinmi Pin àwọn ohùn èlò ìrànlọ́wọ́ fún àwọn àgbẹ̀ ìgbèríko ni ìjọba ìbílẹ̀ Ezeagu ni Ìpínlẹ̀ Enugu.

Àwọn méjèjì yìí ni wọn wá láti agbègbè Ezema Mgagbu-owa, ni ìpínlẹ̀ Enugu, wọn sọ wí pé ìdí tí ìrànlọ́wọ́ yìí fi wáyé ní wí pé àwọn fẹ gbé ètò ohun ògbìn Lárugẹ.

Wọn ní o je ohun ìbànújẹ fún àwọn bi àwọn ṣe n ri bi àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń fi iṣé ọ̀gbìn sílẹ̀.

Wọn ní ètò ọ̀gbìn jẹ ohun orísun tí kò ṣe gbàgbé.

Àwọn ohun tí wọn Pin náà ni katakata, ògùn fún ọ̀gbìn,ati owó.

Ozokolo ni anfààní nlá lo wà nínú ètò ọ̀gbìn, nitori bí ebi ba kúrò nínú ìṣẹ́, ìṣẹ́ bi ṣe.

Ó ní àwọn àgbẹ̀ mẹ́rin ni yóò lo sí ilé pẹ̀lú ẹ̀bùn pàtàkì.

Wọn ni gbogbo ìdojúkọ nípa gbìn gbin Isu ni àwọn yóò pe àwọn onimọ fún ki ọ̀nà abayọ na leè wà lórí rè.

Wọn tún ṣe ìlérí wí pé ọdọọdún ni àwọn yóò ma se ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn ìlú.

Aneke wa rọ àwọn ọ̀dọ́ láti láti kojú mọ iṣẹ àgbè fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ọkan lára àwọn àgbẹ̀ náà ọgbẹni Jonex Okongwu dupẹ lọwọ wọn fún ìrànlọ́wọ́ náà, o ní o jẹ igba àkókò tí irú rẹ yóò ṣẹlẹ ṣugbọn o jẹ ǹkan ìdùnnú fún gbogbo awọn pátápátá

Comments are closed.

button