Ètò ilé gbígbé lórílẹ̀-èdè: Ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ṣàtúnyẹ̀wò ilé títà
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń mójútó Iṣẹ́ àti Ilé gbígbé ní Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ètò láti ṣàtúnyẹ̀wò ilé títà lábẹ́ Àgbékalẹ̀ Ilé gbígbé lórílẹ̀-èdè.
O sọ eleyi ninu alaye kan ti o si si ori X rẹ.
Gẹgẹ bi Ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ṣe sọ, igbesẹ atunyẹwo naa jẹ ara eto tuntun fun tita awọn ile ati pe awọn ti o ba nifẹ si yoo ra fọọmu fifi ifẹ han lati ra ile naa, ti o tun wa fikun pe awọn to nifẹ si ti wọn si gba lati fun laarin 2022 ati 2023 le tun kọwe beere fun ni bayii.
Ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ wa pe awọn ti o ba nifẹẹ si lati gba fọọmu Expression of Interest ni ọfiisi ti Adari ile gbigbe lapapọ ati idagbasoke ilu ni awọn ipinlẹ mẹrindin-logoji ati olu ilu lọfẹẹ.

Fun awọn ọmọ Naijiria ti n gbe lokeere, ile iṣẹ naa sọ pe wọn le gba fọọmu tiwọn naa ni ọfiisi alaga igbimọ awọn ọmọ Naijiria ti n gbe lokeere (NIDCOM).