Kérésìmesì: Ààrẹ Tinubu ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ lẹ́yìn kírísítì
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti kí àwọn Kírísítíẹ́nì kú oríire bí wọ́n ṣe ń ṣàjọyọ̀ ọdún Kérésìmesì, tí ó sì sọ pé ìjọba òun yóò túnbọ̀ máa ṣe ìmúṣẹ ètò ìtura láti mú ìdẹ̀rùn bá àwọn tó ní ìpalára jùlọ, ṣátúnṣe lórí ìpọ́njú tó wà nílẹ̀ lọ́wọ́ báyìí àti láti mú ìnira àwọn ọmọ Nàìjíríà kúrò.
Bi o ṣe n ṣajọyọ pẹlu awọn ọmọ lẹyin krisiti, aarẹ ṣalaye pe asiko keresi jẹ igba pataki ninu ọdun fun gbogbo eniyan paapaa julọ awọn kirisitẹni lati ṣajọyọ ireti ati irapada ti o jẹ ami igbe aye Jesus Kirisiti.
Aarẹ Tinubu tun wa sọ pe, fun gbogbo awọn onigbagbọ, asiko Kérésìmesì pese anfaani lati gbadun iwapapọ pẹlu ẹbi, ṣajọyọ igbe aye, ati idunnu ninu ẹbun ifẹ ati ajọṣepọ to mu igbe aye dun.
O wa pe awọn ọmọ lẹyin Kirisiti ni bayii lati ronu lori iwa to dara julọ ti Kirisiti ki wọn si lo iwa daradara Kirisiti fi waasu fun awọn to wa layika wọn, nipa ninawọ si awọn alaini.
O wa n fi ipinnu rẹ da awọn ọmọ Naijiria loju pe oun yoo ṣejọba pẹlu ifọkansin ati erongba to dara.