Aṣòfin tí ń ṣojú agbègbè ìjọba àpapọ̀ Gúsù Ijaw, ti ìpínlẹ̀ Bayelsa, Aṣojú onímọ̀-ẹ̀rọ Rodney Ambioiwei ti sọ pé òun fẹ́ ṣe onígbọ̀wọ́ àbá àti òfin ìlòkulò òògùn. Ó ń sọ èyí níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹnuwò kan ní Abuja.
O sọ pe lẹyin ti oun daabo aṣeyege oun ni ile ẹjọ ko tẹmi lọrun, oun yoo le fọkan balẹ ṣe ojuṣe oun lati ṣanfaani fun awọn ara ilu gẹgẹ bi aṣofin.
O tun sọ pe oun fẹ dawọ le idagbasoke awọn ọdọ nitori pe wọn ni lati gba idanilẹkọ.
Aṣòfin naa ti o ṣapejuwe agbegbe rẹ bi iṣẹ to wa niwaju oun, o sọ pe oun fẹ ki awọn eniyan oun ṣatilẹyin fun oun lati wakọ Gusu Ijaw siwaju.
Aṣofin Ambioiwei, ṣalaye pe oun mọ ipeninija ti n koju awọn eniyan oun paapaa julọ ni abala ijamba ọkọ oju-omi ti o si nireti pe oun yoo ṣatunṣe lori rẹ nipasẹ aba to wa nilẹ ni ile igbimọ Aṣofin.
O ṣalaye pe oun kii ṣe aṣoju ọmọ ẹgbẹ oṣelu oun nikan ṣugbọn ti gbogbogboo.