Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣojú ké pe ilé iṣé elétò ààbò láti fòpin sí ìpànìyàn ní agbègbè Enugu
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣojú Nàìjíríà ti rọ olùdámọ̀ràn lórí ètò ààbò lórílẹ̀-èdè (NSA) àti àwọn àgbà elétò ààbò láti gbé ìgbésẹ̀ fún ìfòpinsí ìpànìyàn, bíba dúkìá jẹ ́àti bí àwọn adigunjalè ṣe ń jíyàn gbé ní agbègbè Ehamufu, ní Gúsù Enugu/ Isiuzo agbègbè ìjọba ìpínlẹ̀ Enugu.
Ipe yii waye lẹyin ifẹnuko lori imọrankan ti Paul Nmamchi, gba lori “wiwa wọrọkọ fi ṣada ni kiakia lori ipaniyan ati bi awọn adigunjale ṣe n jiniyan gbe ni agbegbe Ehamufu, ni Gusu Enugu/Isi-uzo, agbegbe ijọba ipinlẹ Enugu.”
Aṣoju Nmamchi, ninu ariyanjiyan rẹ, sọ pe ipaniyan loorekoore ati ikọlu ni agbegbe Ehamufu, Gusu Enugu/ agbegbe ijọba Isi-Uzo ti ipinlẹ Enugu ti jẹ ki ibẹ wa ninu ewu ni gbogbo igba.
“Ni bii ọdun meji sẹyin, awọn eniyan to ju ẹẹdẹgbẹta lọ lo ti padanu ẹmi wọn, ti wọn si ji ọpọlọpọ gbe ati awọn miiran ti a ko moye wọn, ti wọn si ti ba dukia to to ọpọlọpọ biliọnu naira jẹ”, ni agbegbe naa, ti o ala rẹ wa lẹgbẹ agbegbe Agala ni ipinlẹ Benue.
“Bi awọn adaran ati adigunjale ṣe n ji awọn obinrin gbe, pẹlu awọn ọmọde n pọ si ni agbegbe naa. Awọn adigunjale n ṣiṣẹ ijamba wọn lati inu aginju ti o to ibusọ mẹwaa ti wọn ti sọ di ibugbe ti wọn ti n ṣe aburu fun awọn ara ilu ti ko mọwọ ti ko mẹsẹ.
“Awọn to ni ipalara, awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wa di adojukọ wọn ati ẹni ti o wa ninu ewu julọ nigba ti idagbasoke ajọṣepọ ọrọ-aje, eto ẹkọ ati ipo aabo awọn ara ilu ni agbegbe naa ti fori ṣanpọn.” Aṣoju sọ bayii.
Ile igbimọ tun wa pe ile-iṣẹ to n risi iṣakoso pajawiri lorilẹ-ede (NEMA) lati pese awọn eroja itura fun awọn olufaragba.
Bakanna, o tun wa rọ awọn ile iṣẹ eleto aabo lati ṣẹ awari awọn to wa nidi iwa aburu ni agbegbe naa ki wọn si da ẹjọ to tọ fun wọn.