Faransé sọ dókítà Rwanda tẹ́lẹ̀ rí sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlé-lógún fún pípa ìran kan run
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Dókítà Rwandan kan tẹ́lẹ̀ rí ti fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlé-lógún gbára láti ilé ẹjọ́ Faransé fún ìlọ́wọ́sí ìparun ìran kan ní ọdún 1994.
Sosthene Munyemana jẹbi ipaniyan run, ni Ọjọru, iwa buruku si ọmọniyan ati ikopa ninu rikiṣi lati da awọn ọran yii.
Wọn fi ẹsun biba ijọba fidihẹ kọ lẹta ti yoo ṣamojuto pipa awọn Tutsis kan dokita tẹlẹ ri, ti o jẹ ọmọ ọdun mejidin-laadọrin.
Wọn tun fi ẹsun ikopa ninu ipade ti wọn ṣe lati dooyi ka awọn ara ilu Tutsi ni Gusu Rwandan prefecture ti Butare, nibi ti o gbe nigba kan ri.
Ọgbẹni Munyemana, ti o lọ si Faranse ni oṣu diẹ lẹyin iṣẹ aburu yii, kọ jalẹ pe oun ko ṣe aburu kankan ti agbejọro rẹ si sọ pe awọn yoo pe ẹjọ ko tẹmi lọrun.
Olupejọ ijọba ti bere fun ẹwọn ọgbọn ọdun lasiko ọsẹ mẹfa igbẹjọ ni ile-ẹjọ Assize ni Paris.