Ààrẹ Tinubu ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú adarí orílẹ̀-èdè nígbà kan rí, Buhari ní ọdún kọkànlé-lọ́gọ́rin
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu ti ṣàpèjúwe ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà Muhammadu Buhari, bíí àwòkọ́ṣe ìfaradà, ìfọkànsìn, ẹni tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè rẹ̀ àti tí ó tún lọ́kàn tó mọ́ sí orílẹ̀-èdè, bí ó ṣe ń ṣàjọyọ̀ ọdún kọkànlé-lọ́gọ́rin rẹ̀.
Nigba ti o n sọrọ nipa aarẹ Buhari, adari Nàìjíríà wa gboriyin fun ijẹrisi iṣakoso ati awọn aṣeyege aarẹ tẹlẹ ri naa, ti o si n ranti bi o ṣe sin orilẹ-ede ni asiko ọtọọtọ gẹgẹ bii adari orilẹ-ede ati bii aarẹ.
Ninu alaye kan ti agbẹnusọ rẹ, Ajuri Ngelale, buwọlu aarẹ Tinubu gboriyin fun aarẹ tẹlẹ ri Buhari, fun akitiyan rẹ lori ipese amayedẹrun bii awọn papakọ ofurufu tuntun kariaye, oju rin, iṣagbedide Ebute tuntun, dọsinni daamu tuntun, ibudo ipese ina mọnamọna, epo ile ati gaasi amayedẹrun, opopona marosẹ ati afara loriṣiriṣi jakejado Naijiria.
Aarẹ naa tun wa gboriyin fun adari nigba kan ri, Buhari fun idasilẹ eto aabo katakara awujọ ní Naijiria lapapọ, ati awọn aṣeyege miiran.