Bí gbogbo àgbáyé ṣe ṣayẹyẹ àyájọ́ àwọn Abarapá ní ọjọ́ kẹta, oṣù kejìlá, 2023, ni ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ abarapa ní Nàìjíríà ń pè fún kí àwọn náà wà lára olùkópa nínú àwọn ètò ọmọnìyàn.
Ẹgbẹ Akojọpọ awọn Abarapa lorilẹ-ede (Jonapwd) ní ipinlẹ Kaduna ní ajọṣepọ pẹlu Akojọpọ Ẹgbẹ iṣakoso, Alaafia, Ironilagbara ati Idagbasoke (CALPED), ṣe agbekalẹ eto ibaraẹnisọrọ pẹlu ọpọlọpọ ni ipinlẹ naa, lati ṣajọyọ ọjọ naa, ti wọn si tun wa rọ awọn to nii ṣe lati maa tenumọ igbẹnusọ fun pe ki awọn naa wa lara olukopa ninu awọn eto ọmọniyan.
Ayẹyẹ yii waye ni ibudo Atunṣe ti Kaduna, ti wọn si tun rọ awọn oniroyin naa lati jẹ ki awọn eniyan mọ pataki ki awọn abarapa naa wa lara awọn eto ọmọniyan.
Alaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ, Comrade Suleman Abdulazeed, sọ idi ti awọn abarapa (PWDs) ní Naijiria ṣe ni lati kopa.
Akọle Ajayọ awọn Abarapa Kariaye (IDPD) 2023 ní: “Ka ni iṣọkan lati ṣagbasilẹ ati ṣaṣeyege lori SDGs fun, pẹlu, ati diduro ti awọn Abarapa.”
Leave a Reply