Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara, Àríwá Àringbùngbùn Nàìjíríà, nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ akitiyan rẹ̀ láti jẹ́ kí àwọn ìwà ìbàjẹ́ kúrò nílẹ̀, ti ṣàpèjúwe títọrọ àti bí àwọn alárùn ọpọlọ ṣe ń rìn káàkiri lórí títì bí ohun tí kò dára rárá àti pé ó tún jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu láwùjọ.
Kọmiṣọna fun idagbasoke Ibaraẹniṣepọ, Ọpẹyẹmi Oluwakẹmi Afọlashade sọ eyi kasiko ipari eto kiko nilẹ ti ile iṣẹ ijọba apapọ ti ipinlẹ naa ṣe larin olu ilu.
Afọlashade banujẹ lori iwa aburu titọrọ lori titi ti wọn ti sọ di ọrọ aje gidi laarin awọn eniyan kan, lẹyin ọpọlọpọ ijumọsọrọ, itaniji awọn oniroyin, ati oriṣiriṣi agbekalẹ ti ijọba ṣe lawujọ fun awọn abarapaa ati awọn to nipa lara ni ipinlẹ naa.
“Eto kiko nilẹ yii jẹ ara ojuṣe ile iṣẹ naa ati ọna lati tunbọ ri pe awujọ mọ lọwọ iwa aburu awujọ, ti eyi ṣi n ṣe igbelarugẹ imọtoto agbegbe ati ọwọ ti a ni fun ipinlẹ,” Kọmiṣịna sọ bayii.
O tunbọ ṣalaye pe ipinlẹ Kwara ko ni faaye gba itọrọ lori titi nitori pe o lodi si ofin ipinlẹ naa; o jẹ iwa ọlẹ, ti rinrin kaakiri awọn to larun ọpọlọ naa si lewu fun awujọ.
Leave a Reply