Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Ọṣun buwọ́lu owó oṣù fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn tí ń gba owó ìsinmi

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 194

Gómìnà Ademọla Adeleke ti ìpínlẹ̀ Ọṣun ti buwọ́lu sisan owó oṣù fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn tí ń gba owó ìsinmi gẹ́gẹ́ bíi ìgbésẹ̀ láti dásí ipa ìmúkúrò àdínkù owó orí epo ilẹ̀.

Nini alaye kan ti agbẹnusọ gomina, Malam Ọlawale Rasheed, buwọlu, Adeleke sọ pe iṣe naa jẹ ara ipinnu rẹ si igbe aye rere awọn oṣiṣẹ ati imuṣẹ ipinnu fifunni ni ohun iranwọ lati din ipa ìmúkúrò àdínkù owó orí epo ilẹ̀ ku.

Ibuwọlu naa ti o wa ninu lẹta  kan ti wọn pin kaakiri  lati ile iṣẹ ijọba ti n mojuto Orisun eniyan ati Ironiyan lagbara, sọ pe awọn oṣiṣẹ yoo gba ẹgbẹrun mẹẹdogun Naira loṣu, ti àwọn tí ń gba owó ìsinmi yoo si gba ẹgbẹrun mẹwaa Naira.

Lẹta naa ti Akọwe pataki  ile iṣẹ ijọba naa, Sunday Olugbenga Fadele buwọlu sọ pe owo oṣu naa yoo waye fun oṣu mẹfa, ti yoo si bẹrẹ ni oṣu kejila.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button