Olùdíje ipò gómìnà fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ní ìpínlẹ̀ Edo, Ọ̀gbẹ́ni Anslem Ojezua, ti sọ pé òun yóò ra abala ètò ẹ̀kọ́ padà tí òun yóò sì tún ṣe àmójútó ìgbé ayé àlàáfíà àwọn olùkọ́ni, tí wọ́n bá dìbò yan òun. Ojezua ṣe ipinnu yii nigba ti o n dahun si ibeere awọn ọmọ ẹgbẹ oniroyin ti ile isin ni ọjọ Aiku, ni olu ile isin, ni Ogbesasa, Benin, olu ilu naa.
Kọmiṣọna fun eto ibaraẹnisọrọ ati ifihan nigba kan ri sọ pe abala ẹkọ yoo wa lookan aya oun, o sọ bayii “Ọrọ ẹkọ jẹ mi logun pupọ.
“Ọrọ ẹkọ ṣe pataki si mi, paapaa julọ alakọbẹrẹ; ni tori pe a ni ile iwe to pọ ṣugbọn ti awọn olukọni ko to.
“Ni ọpọlọpọ igba, o le jẹ nitori pe o farajọ pe ipinlẹ ko ni agbara lati san owo fun iye awọn olukọni to to.
“Ṣugbọn a o wa ọna lati ṣe e.Bawo ni a o ṣe ni awọn olukọni to to?
“Bawo ni a o ṣe jẹ ki awọn alugbe da si, ki awọn ọmọ wa le ni anfaani si ẹko to muna doko?”
Leave a Reply