Adarí Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Kaduna kí Gómìnà Uba Sani kú oríire
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Adarí Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Kaduna ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn án, Aṣòfin Yusuf Zailani ti kí Gómìnà Uba Sani kú oríire lórí àṣeyọrí rẹ̀ ní ilé-ẹjọ́ kò tẹ́mi lọ́rùn.
Ninu alaye kan ti oluranlọwọ pataki rẹ lori eto ibaraẹnisọrọ ati ipolongo, Aṣoju Ibrahim Danfulani fi sita, o sọ pe aṣeyege Gomina Sani kii ṣe fun ara rẹ nikan ṣugbọn fun gbogbo ipinlẹ Kaduna.
Adarí Ilé ìgbìmọ̀ naa wa gboriyin fun gomina lori ifọkan igbe aye to dara ati idagbasoke awọn eniyan, leyi ti o jẹ yọ lati igba to ti de ipo, ni ọjọ kọkandin-lọgbọn, oṣu karun un.
Aṣoju Zailani, ti wọn mọ fun ifaraṣiṣẹ fun ara ilu ati ipa rẹ ni ṣiṣeto alaafia laarin awọn ọmọ ile igbimọ, wa yanana pataki aṣeyege Gomina Sani.
O sọ pe kii ṣe pe o tunbọ fẹsẹ igbagbọ ati igboya awọn eniyan ninu iṣejọba gomina naa mulẹ nikan, ṣugbọn tí ó tún jẹ́ bíi ẹ̀rí fun ifọkansi rẹ to muna doko si ilọsiwaju ipinlẹ Kaduna.
Leave a Reply