Àwọn aṣòfin gbóríyìn fún ẹgbẹ́ òsìṣẹ́ bí wọ́n ṣe fòpin sí ìyanṣẹ́lódì
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú ti gbóríyìn fún ìgbésẹ̀ tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ gbé láti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n rawọ́ lé láti ọjọ́ méjì sẹ́yìn jákèjádò orílẹ̀-èdè.
Ninu alaye kan ti alaga igbimọ awọn oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Aṣofin Adegboyega Adefarati ati agbẹnusọ ile/ Alaga igbimọ fun ibaraẹnisọrọ ati ọrọ ilu, Aṣofin Akin Rotimi kekere jọ buwọlu, ile igbimọ tun gboriyin fun ọfiisi oludamọran lori aabo lorilẹ-ede fun akitiyan rẹ lati ri pe iyanṣẹlodi naa wa sopin fun anfaani awọn ọmọ Naijiria.
“Nitori pe iyanṣẹlodi yi ka wọn lara layi ti o pa eto ọrọ-aje lara ni ibi ti o pọ lorile-ede, ohun lo fa ki ile igbimọ gbe igbeṣẹ lati da sii ọrọ naa, ni Ọjọọru nipa biba awọn to niiṣe sọrọ bi yoo ṣe ni iyanju.
Awọn ọmọ ẹgbẹ ti ṣalaye pe ẹgbẹ oṣiṣẹ (NLC), ẹgbẹ awọn oni karakata (TUC) ati awọn ẹgbẹ to so mọ ti bẹrẹ iyanṣẹlodi jakejado orilẹ-ede ni ọjọ Iṣegun, ọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, lati fi ẹhonu wọn han lori lilu ti wọn lu aarẹ NLC ati awọn nnkan miiran.
Leave a Reply