Ẹgbẹ́ Tiv pè fún àlàáfíà láàrin àwọn àgbààgbà tó níkùn sínú síra wọn ní ìpínlẹ̀ Nasarawa
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ẹgbẹ́ ìdàgbàsókè Tiv (TIDA), tó wà lábẹ́ àbojútó àwọn ọmọ bíbí inú Tiv ti ìpínlẹ̀ Nasarawa, ti rọ àwọn ọmọ olókìkí méjì rẹ̀, Aṣòfin Boniface Ifer àti Asọ̀fin Peter Ahemba, láti yanjú aáwọ̀ tó wà láàrin wọn nítorí àwọn ènìyàn wọn àti ìpínlẹ̀ náà lápapọ̀.
Ifer ati Ahemba, ti awọn mejeeji fi igba kan jẹ aarẹ TIDA, ti n ni ariyanjiyan lori awọn ọrọ to jẹ mọ awọn eniyan Tiv ní ipinlẹ naa.
Ifer ti fi ẹsun pe Ahemba ko ja ipeninija ti n koju awọn eniyan oun ni ipinlẹ naa kunra nitori bi wọn ṣe ṣẹṣẹ yan ni agba igbakeji oluranlọwọ pataki lori ọrọ ara ilu si Gomina Abdullahi Sule, ṣugbọn ti Ahemba si taku pe oun ti ṣe ipa oun gẹgẹ bi ọmọ Tiv to niiṣe lotitọ, ati gẹgẹ bí ẹni ti ijọba ipinlẹ Nasarawa yan.
Nigba ti o n dasi ọrọ naa ninu alaye kan ti o fi sita fun awọn oniroyin ni Lafia, aarẹ TIDA ni ipinlẹ naa lọwọ bayii, Asofin Solomon Chunku, wa rọ awọn awọn mejeeji lati fopin si ija naa, ki eyi maa baa da wahala silẹ laarin awọn eniyan Tiv ní ipinlẹ naa.
Leave a Reply