Take a fresh look at your lifestyle.

Àṣeparí ìdìbò gómìnà : Alága INEC rọ àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìdìbò láti ṣe iṣẹ́ wọn bíi isẹ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 206

Alága ìgbìmọ̀ olómìnira tó ń mójútó ètò ìdìbò lórílẹ̀-èdè, INEC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu ri rọ àwọn òṣìṣẹ́ ìgbìmọ̀ náà láti ṣàfihàn bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn àti ìmọṣẹ́ wọn bíi iṣẹ́.

O pe ipe yii ni lasiko ti ko to wakati mẹrinle-logun si àṣeparí ibo gomina ipinlẹ Bayelsa, Imo ati Kogi ti o kù.

Alaga INEC sọ bayii. “Bi mo ṣe sọ leralera, lasiko awọn abẹwo ayẹwo  imojuto ti mo ṣe si awọn ipinlẹ mẹtẹẹta lai pẹ, INEC kii ṣe ẹgbẹ oloṣelu ti a ko si ni oludije kankan ninu idibo naa.

“Ojuṣe tiwa ni lati daabobo eto ati lati fun gbogbo ẹgbẹ oloṣelu ati oludije ṣafihan ara wọn. Yiyan ẹni ti yoo jẹ gomina ipinlẹ Bayelsa, Imo ati Kogi wa lọwọ awọn oludibo,” o sọ bayii.

Ọjọgbọn Mahmood sọ pe igbimọ eleto idibo naa pese awọn ohun elo idibo to ṣe pataki ati awọn miiran fun idibo.

Mahmood tun wa sọ pe awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti yoo sisẹ lọjọ naa ti gba idanilẹkọọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button