Àṣeparí ìdìbò: Àgbékalẹ̀ ẹ̀tọ àwọn akọ̀ròyìn pè fún ìdáábòbò ẹ̀tọ̀ àwọn oníròyìn
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àgbékalẹ̀ ẹ̀tọ àwọn akọ̀ròyìn (MRA), ti rọ ìjọba Nàìjíríà ní gbogbo ìpele, àwọn Agbófinró àti àwọn ilé-isẹ́ aláàbò láti sa gbogbo ipá wọn láti dáábò bò àwọn akọ̀ròyìn àti àwọn òṣìṣẹ́ oníròyìn mìíràn, lásìkò àṣeparí ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa, Imo àti Kogi ní òpin ọ̀sẹ̀.
Ẹgbẹ naa sọ pe ojuṣe àwọn oniroyin lati pese ijabọ lori eto idibo ṣe pataki fun
ibo lọ nirọọrun, ni otitọ ti o si han gbangba kedere si gbogbo eniyan.
Ninu alaye kan ti o fi sita ni ilu Eko lori idibo naa, MRA rọ awọn akọroyin lati ṣọ ara wọn, ki wọn o si lo awọn opo ibaraẹnisọrọ kiakia lati fi ewu tabi ikọlu kan kan ti o ba koju wọn ni gbogbo asiko eto naa ati eyikeyi ipeninija to ba koju igbe idibo naa safẹfẹ, to aye leti.
Leave a Reply