Ìpínlẹ̀ Sokoto : Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ jáde fi oyè yẹ́ alákóso olùdásílẹ̀ sí, àwọn mìíràn
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé-èkọ́ gíga Fáfítì Usman Danfodio ti fi oyè yẹ́ alákóso olùdásílẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sai’du Galaganchi àti àwọn tí wọ́n wá lẹ́yìn rẹ̀ si.
Awọn miiran ti wọn tun foye yẹ si ni, ọmọ orilẹ-ede ti n ṣoju Naijiria fun Ajọ Iṣọkan Agbaye, Ọjọgbọn Tijjani Bande ati Emir ti Yauri, Dokita Muhammad Zayyanu Abdullahi.
Awọn to ku ni: Ọjọgbọn Mahdi Adamu Ngaski, Ọjọgbọn Abubakar Gwandu, Ọjọgbọn Aminu Mika’ilu, Ọjọgbọn Riskuwa Shehu, Ọjọgbọn Abdullahi Abdu Zuru ati alakoso ile ẹkọ naa lọwọ bayii, Ọjọgbọn Lawal Bilbis.
Wọn fun wọn ni ami ẹyẹ naa nibi apejọ apapọ ẹlẹekeje ati idibo awọn alaṣẹ tuntun ti o waye ni gbọngan Fafiti naa.
Ninu ọrọ rẹ, alakoso Fafiti naa, Ọjọgbọn Lawal Bilbis, wa sọ pataki ti Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé-èkọ́ gíga Fáfítì fi nilo lati wa ṣe iranlọwọ fun ile-iwe naa nipa kikọ awọn ibugbe awọn akẹkọọ ati lati ṣe iranlọwọ owo fifun fun awọn akẹkọọ to wa nibẹ lọwọ bayii.
Bilbis wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati tunbọ dira wọn loṣuṣu ọwọ fun ilọsiwaju eto ẹkọ ati ti ile iwe naa.
O tun wa gba awọn ọmọ ẹgbẹ naa nimọran lati ran awọn ile –iwe ti wọn ti la kọja lọwọ.
Leave a Reply