Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé ìgbìmọ̀ Nàìjíríà yóò ṣe ìpàdé pàjáwìrì ní ọjọ́ Ajé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 187

Ilé ìgbìmọ̀ Nàìjíríà yóò ṣe ìpàdé pàjáwìrì ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹfà, osù kọkànlá 2023, láti buwọ́lu ìbò àti àwọn ababọ ètò tí wọ́n ṣe níbi ìjókóo Ọjọ́ọ́rú tó kọjá.

Ile igbimọ n gbero lati buwọlu ijabọ igbimọ ile to n risi inawo lori iye owo to le ni tiriọnu meji ofin afikun inawo fun ọdun 2023, nibi ipade ti wọn ṣe kẹyin.

Ile-igbimọ to ga julọ tun ṣe agbeyẹwo ati ibuwọlu awọn mẹta ti aarẹ Bọla Ahmed Tinubu buwọlu fun yiyan ni alakoso igbimọ olominira ti n mojuto eto idibo lorilẹ-ede (INEC).

Wọn ti sun Ipade pajawiri ti o yẹ ko waye tẹlẹ lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrin, oṣu kọkanla 2023, si ọjọ Aje.

Alaga, igbimọ ile lori ibaraẹnisọrọ ati ipolongo, Sẹnetọ Yẹmi Adaramodu fi idi eyi mulẹ pe ile-igbimọ yoo ṣepade lọjọ Aje.

Nigba ti wọn beere boya sisun afikun ofin inawo wa lara idi ipade pajawiri naa, Adaramodu sọ pe gbogbo nnkan ti ile igbimọ ṣe ni Ọjọọru ni o wa lara rẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button