Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin bẹnu àtẹ́ lu fífi àwọn ọ̀dọ́ bìnrin rúbọ

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 222

Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú  ṣòfin ti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí bí wọ́n ṣe ń pa àwọn ọ̀dọ́ bìnrin láti fi rúbọ.

Ile igbimọ naa tun banujẹ lori pe awọn ọdọ kunrin ni o n hu iwa aburu yii, ti o si jẹ wipe wọn le maa le da iṣe naa ṣe funra wọn ṣugbọn pẹlu awọn baba n gbẹjọ. O tun wa jẹ ẹdun ọkan pe awọn ọdọ binrin Naijiria ti wa wa ninu ewu bayii.

Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú  ṣòfin wa pe ọga agba awọn Agbofinro lapapọ lati gbe igbimọ kan dide ti yoo ṣe iwadi lato foju awọn baba n gbẹjọ to wa nidi ipaniyan yii, ki wọn o si ṣe idajọ to yẹ fun wọn.

O tun wa pa laṣẹ fun igbimọ ile lori ifaramọ iṣofin lati ri pe wọn fọwọ sowọpọ pẹlu ọna abayọ ti wọn ba la kalẹ.

Ọna abayọ yii wa lẹyin Ọrọ pataki Pajawiri Ara ilu (Order 8 Rule 4) lori ọna lati koju aburu to n ṣẹlẹ lọwọ bayii, ti wọn n fi awọn awọn ọdọ binrin rubọ ni Naijiria, ti: Aṣofin Awaji-Inombek D. Abiante da àbá rẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button