Gaza: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù Israeli ní ibùdó àwọn tí wọ́n sálọ sí ilẹ̀ mìíràn fún ààbò
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àwọn Ẹgbẹ́ aṣàánú ti bẹnu àtẹ́ lu bí Israel ṣe kọlu ibùdó àwọn tí wọ́n sálọ sí ilẹ̀ mìíràn fún ààbò ní Jabalia, tí ó sì sọ pé ìkọlù alátẹ́gùn náà yẹ kó jẹ́ “ìtanijí” fún àwọn adarí lágbàáyé láti pè fún ìdádúró ogun náà ní Gaza.
O kere ju, ọgọrun ọmọ Palestinie lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti Israel kọlu agbegbe kan to lero pupọ, to mule ti Ariwa Gaza Strip, ti ile-iṣẹ ijọba ti n mojuto eto ilera ṣapejuwe rẹ bii“ipaniyan Israeli to burujai”.
Oludari ile iwosan Indonesia sọ pe wọn pa ọpọlọpọ ti awọn miiran si farapa ninu ikọlu naa; onimọ ẹrọ iroyin Al Jazeera padanu awọn ẹbi rẹ mọkandin-logun ninu ikọlu naa.
Wọn ti ge Ile-iṣẹ ibaraẹnisọrọ Paltel Palestine ati eto ayelujara danu jakejado Gaza lẹẹkansi.
Ọpọlọpọ awọn ọmọ Palestine to farapa yoo kuro ni agbegbe naa ni Ọjọọru nipasẹ sisọda si Rafah lati lọ gba itọju ni awọn ile iwosan Egypt, gẹgẹ bi ile iṣẹ to n mojuto aala ni Gaza ṣe sọ.
Leave a Reply