Take a fresh look at your lifestyle.

Alága àpapọ̀ APC yan SSA tuntun fún ìdánilẹ́ékọ́ ará ìlú

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 195

Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Dókítà Abdullahi Umar Ganduje ti yan àgbà akọ̀ròyìn, Olóyè Oliver Okpala gẹ́gẹ́ bí àgbà igbákejì pàtàkì rẹ̀  fún ìdánilẹ́ékọ́ ará ìlú.

Iṣẹ rẹ si ti bẹrẹ ni kiakia lati ọjọ kinni, oṣu kọkanla 2023.

Oloye Oliver Okpala ti ṣiṣẹ bii akọroyin ni ile iwe iroyin ati ile iṣẹ mohun maworan, le ni ọdun marunle-logoji.

O tun ti siṣẹ bii oludamọran lori ibaraẹnisọrọ fun gomina ipinlẹ Ebonyi tẹlẹ ri, Dokita Sam Egwu ati bii bí àgbà igbákejì pàtàkì lori ibaraẹnisọrọ ati  ijumọsọrọ ọgbọn si gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ri, Oloye Willy Obiano ti o si tun figba kan jẹ oludamọra lori ile-iṣe akọroyin si alaga apapọ PDP tẹlẹ ri, Dokita Bamanga Tukur.

Akọwe apapọ fun ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Surajudeen Ajibola Basiru ni o buwọlu iwe igbanisisẹ rẹ.

Pẹlu ọpọlọpọ iriri lẹnu iṣẹ akọroyin, ko si isiye meji lori pe Oloye Okpala yoo ṣiṣẹ rẹ  tuntun bii iṣẹ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button