Mínísítà fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pè fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè lẹ́yìn ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ tó ga jùlọ
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Mínísítà Nàìjíríà fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ìfihàn lápapọ̀, Mohammed Idris ti rọ gbogbo ẹgbẹ́ olóṣèlú àti àwọn àgbààgbà ìlú láti mójú kúrò lórí ìdìbò, kí wọn ó sì gbájúmọ́ bí orílẹ̀-èdè yóò ṣe dàgbàsókè.
Ninu ọrọ rẹ nibi apejọ awọn akọroyin, ni ọjọ Ẹti, ni Abuja, Minisita sọ bayii “ni bayii ti ifigagbaga ofin lori esi ibo aarẹ ti pari, o ti ya bayii lati parapọ fun idagbasoke, si abala iṣakoso ti ko ni idiwọ.”
Nigba ti o n ba awọn akọroyin sọrọ lori bi o ṣe n lọ lorilẹ-ede, Minisita gba pe eto ọrọ-aje ko ri boṣe yẹ ko ri lagbaaye ti o si pe pe gbogbo eniyan lo nipa ti yoo ko lati koju ipeninija naa.
O tun wa n mu daniloju pe “Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti fi sọ pe oun yoo jẹ aarẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria: laibikita agbegbe, ẹya, ẹgbẹn, tabi ẹsin ti eeyan n sin.”
Leave a Reply