Adarí orílẹ̀-èdè German Olaf Scholz, yóò ṣàbẹ̀wò sí Nàìjíríà ní ọjọ́ kọkàndín-lọ́gbọ̀n àti ọgbọ̀njọ́, oṣù kẹwàá 2023.
Ninu atẹjade kan lati ile-iṣẹ ti n ṣoju German ni Naijiria, idi abẹwo naa si ni lati tunbọ fidi ajọṣepọ orilẹ-ede mejeeji mulẹ.
Nigba ti o ba wa ni orilẹ-ede, Adari Scholz yoo ṣepade pẹlu aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ati Aarẹ Ajọ igbimọ ECOWAS , Dokita Omar Alieu Touray, ni Abuja.
Yoo wa gbera lọ si ilu Eko ti yoo ti ṣe ifilọlẹ apejọ katakara Ọrọ-aje Naijiria-German.
Lasiko to ba wa L’eko, yoo ṣe ipade pẹlu ẹgbẹ ara ilu ni Naijiria pẹlu awọn oniṣowo to ṣe n bẹrẹ.
Pẹlu awọn aṣoju, Chancellor Scholz yoo lopa ninu irin-ajo ilu Eko lati foju ri awọn ipeninija ati anfaani ti o wa ni ilu pataki bii ilu Eko.
Leave a Reply