Ààrẹ Bọla Tinubu ń darí àpèjọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta ti ìjọba rẹ̀ ní gbọ̀ngàn ilé 0rílẹ̀-èdè, Abuja.
Apejọ naa, eyi ti o bẹrẹ ni nnkan bii agogo mẹwaa owurọ ni Akọwe fun ijọba apapọ, George Akume; Ọga agba fun awọn oṣisẹ ijọba apapọ, Dokita Fọlashade Yẹmi-Ẹsan; Ọga agba fun awọn oṣiṣẹ aarẹ Asofin Fẹmi Gbajabiamila, Oludamọran fun eto aabo lorilẹ-ede, Nuhu Ribadu wa nijooko nibẹ.
Awọn ti ko si nibẹ ni igbakeji aarẹ, Kashim Shettima ti o n kopa ninu apejọ ounjẹ agbaye ni Amẹrika ati awọn Minisita kan bii ; Aṣa ati ọrọ-aje iṣẹ ọwọ, Hannatu Musawa; Minisita fun irin ajo kiri, Lola Ade-John, ati awọn miiran.
Ni ọjọ Aje to kọja, Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati ikọni lorilẹ-ede, Mohammed Idris, kede pe ipade igbimọ yoo maa waye ni ọjọ Aje lati igba yii lọ, ti ko si ni maa waye ni Ọjọbọ mọ, bii ti tẹlẹ.
Idris ṣalaye pe ipade igbimọ naa le maa maa waye ni ọsọọsẹ, ayafi ti o ba pa dandan.
Leave a Reply