Take a fresh look at your lifestyle.

Kogi 2023: Ìfàsẹ́yìn bá LP bí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlé-lógún ṣe darapọ̀ mọ́ APC

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 318

Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour, LP ti rí Ìfàsẹ́yìn bí gbogbo àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlé-lógún rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kogi ṣe darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC.

Awọn alaga naa darapọ mọ ẹgbẹ to n ṣejọba, APC pẹlu ọgọọrọ awọn ololufẹe wọn.

Ijabọ fidi ẹ mulẹ pe alaga APC ti ipinlẹ naa, Alhaji Abdullahi Bello, ṣe itẹwọgba didarapọ wọn ni Ile Lugard, ní Lokoja.

Adari awọn ti o fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ, Ọgbẹni Awẹ Kayọde, sọ pe awọn gbimọ lati darapọ mọ APC fun atilẹyin oludije gomina ẹgbẹ naa, Usman Ododo, ninu ibo gomina ọjọ kọkanla, osu Belu ti o n bọ lọna yii.

Kayoọde tun wa sọ pe kikuro ninu ẹgbẹ naa tun wa ṣe pataki nigba ti wọn ri pe LP ko ṣe pataki ni ipinlẹ naa mọ.

Idi miiran fun kikuro wa ni idaniloju pe oludije APC , Usman Ododo, jẹ ẹni ti o ni iṣọkan ti wọn si nilo iru iwa bẹẹ fun itẹsiwaju awọn aṣeyọri ti gomina Yahaya Bello ti ṣe.

Mo ti wa ninu ẹgbẹ APC telẹ ki n to darapọ mọ ẹgbẹ Labour. Mo ti pada de bayii pẹlu ọpọlọpọ eniyan ti a o si ṣe daradara si ẹgbẹ naa. LP ri ibo ti o fẹẹ to ọgọrin ẹgbẹrun ninu idibo aarẹ to kọja lọ; awọn eniyan kannaa ti o siṣẹ aṣeyọri naa ṣi wa.

Bakannaa, alaga ijọba ibilẹ Bassa fun ẹgbẹ Labour, ti o tun jẹ alaga ẹgbẹ LP fun igbimọ awọn alaga, Jimba Emmanuel, wa sọ pe ẹgbẹ oṣelu kan jẹ pẹpẹ lati ṣe ijọba ni.

O sọ pe ijọba to dara da lori ifẹ inu onikaluku lori idagbasoke ati mimu ere ijọba tiwantiwa ba awọn eniyan.

O wa sọ pe oludije gomina LP ko ni iwa ti o tọ, ni eyi ti o fa igbesẹ wọn lati fi ẹgbẹ naa silẹ “ọkọ̀ ojú omi tí ń rì”.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button