Gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa búra fún àwọn olùrànlọ́wọ́ pàtàkì mẹ́tàlé-lọ́gọ́rùún
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa ti búra fún àwọn olùrànlọ́wọ́ pàtàkì tó lé lọ́gọ́rùún tun tun ní orísiríṣi ipele.
Yiyan yii jẹ ọkan lara ìṣe ni gbogbo igba lati tunbọ fun awọn ohun elo ijọba lagbara lati ṣiṣé wọn boṣetọ ati bi oṣe yẹ.
“Gbogbo ẹyin ti wọn ṣẹṣẹ yan, mo fẹ ki yin ku oriire gẹgẹ bi oluranIọwọ pataki. Wọn yan yin laarin ọpọlọpọ orisun to wa ni ipinlẹ. Ti wọn si mu yin laarin awọn to kunju osunwọn nitori pe o ti wa ninu akọsilẹ pe asiko ti to lati sin awọn eniyan ipinlẹ Adamawa. A wa gbọdọ mojuto akọsilẹ yii pẹlu imoore ti o tọ,” Gomina Fintiri sọ bayii.
“Osunwọn yiyan awọn oloṣelu mi da lori ikunju osunwọn, itọkasi lati igberiko, isododo ati ju gbogbo rẹ lọ ifẹmi imoore han,”.
O wa n sọ fun awọn oluranlọwọ pataki naa pe, wọn n reti wọn lati lo ọpọlọpọ iriri wọn lati ṣe ojuṣe tuntun yii, ki wọn o mu gbogbo ipinlẹ naa gẹgẹ bi agbegbe wọn, ki wọn o si ṣe ododo pẹlu gbogbo eniyan ati ni yiyanju ọran lọna to tọ.
Gomina Fintiri wa rọ wọn lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn Kọmiṣọna, awọn adari lorisiriṣi ati awọn igbimọ pataki miiran, fun aṣeyọri lori ṣiṣiṣẹ fun awọn eniyan boṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
Leave a Reply